Ilana fun gbogbo ara ilu nipa bi a se le dena titankale arun korona ni ayika ati ayida wa, ni ibudoko wa gbogbo, ninu oko ero, korope, alupupu, tabi keke elese meta.
Igbiyanju yi wa lati se iranlowo fun ilakaka awon alamojuto akanse ise lojuponna ati dekun ajakale aisan buruku yi ni ibu ati ooro ipinle Osun.
Ile ise ode ati igbokegbodo oko ti ipinle Osun fi n to gbogbo ara ilu leti pelu ikede ati awon Ilana ti o di dandan fun olori ati elemu lati tele lati asiko yi lo.
1. Gbogbo awako ati alamojuto ibudoko gbodo mojuto imototo ti o peye ni ibudoko won ni gbogbo igba ki won to bere ise tabi irin ajo won ati nigbati won ba pari ise oojo won.
2. Gbogbo awako ati alamojuto ibudoko gbodo pese omi ati ose fun fifo owo won daadaa ati lilo ohun ipawo ti o n dena ajakale arun korona vairusi yi ( hand sanitizers).
3. Won si gbogbo ri i daju pe awako, agbero ati gbogbo ero oko ni o n si se imototo yi ni igbakuugba.
4. Gbogbo awako ati alamojuto ibudoko gbodo ri daju pe won ko fi aaye gba gbigbe ero koja Ilana ti a la kale fun oniruuru ohun irinna wonyi:
– Alalupupu ( Okada ) – ero kan.
– Keke elese meta – ero meta.
– korope – ero marun.
– oko akero ( 18 passenger bus) – ero mesan .
O se pataki ki a fi alafo ti o to ese bata meji sile laarin ero meji ti won joko si ibi kan na .
Eleyi wa ni ibamu pelu Ilana Ile ise ijoba apapo ti o n mojuto didekun ajakale aisan ( NCDC).
A si gbodo jina si enikeni ti a ba fura si pe o ni aisan korona vairus yi ni iwon ese bata marun.
5. Ko si gbodi si diduro ero ninu oko kankan ( No standing in public mass transit).
6. Eleyi tumo si pe ko gbodo si akodenu ero ninu oko.
7. Gbogbo awako ati agbero gbodo wo ibowo ati ibomu nigbati oko ba n lo loju popo .
8. Gbogbo oko ero ni o gbodo ni ero (thermomeyer) ti a fi nye ara ero wo ki won to bo sinu oko.
9. A ro gbogbo awako, awon Ile ise ti won n fi oko ero se ise ati alamojuto ibudoko ki won o pe akiyesi ijoba si enikeni ti won ba fura si pe o ni aisan korona vairus yi nipa pipe si ori awon ero ibanisoro wonyi:
Ile ise ode ati igbokegbodo oko ti ipinle Osun; 07061061154
Ile ise itoju alaisan ara ilu: 08033025692, 08033908772, 08056456250.
Ile ise ijoba ti o wa fun pajawiri 293.
10. A ro gbogbo ara ilu lati ta ijoba ni olobo nipa enikeni ti ko ba pa awon Ilana ti a ka sile yi mo. E le fi oro na to awon agbofinro leti pelu.
O da wa loju pe pelu ifowosowope gbogbo ara ilu, a o le pawopo fi opin si ajakale arun yi ni awujo wa.
Mo dupe lowo yin.
Emi ni Onimo ero Hussein Olatoke Olaniyan
Olubadamonron Pataki fun Gomina ipinle Osun Lori ise ode ati igbokegbodo oko.